Aladikun Adimula

Aladikun Adimula

Share

Protection, Knowledge, Breakthrough, Infertility, Business Success, Fruitfulness

Photos from Aladikun Adimula's post 03/06/2023
Photos from Aladikun Adimula's post 01/06/2023

Aladikun Agba Ilua. :Irosunturupon /Irosun Etutu. :Tutudundun Tutunini, adifa fun Osupa rogodo ti won ni ko ru Ebo Iyin kari Aye. Olodumare a so wa di Eni iyin lawujo ati ni gbogbo Aye. Aladikun Italeke Irumole Oosa Ilua

Photos from Aladikun Adimula's post 01/06/2023

Aladikun Italeke Agba. :Owonrin rosun :Gbedugbedugberegede, adifa fun Onitude kugu Oju Abe, mojiyan ni ile Onitude moyo, mo je Eran ni ile Onitude moyo, mo mu Oti ni ile Onitude moyo, mo tun fi Omo Onitude se Aya, Ewu Onitude mo wo si orun, iku ti yio pa Onitude kowaawi fun Awo. Ase Ifa yii wa lenu gbogbo Awo. Ifa so wipe ire gbogbo, Ifa so wipe isegun ota. Kia fi opolopo ounje Orisiirisi pelu oti Elerindodo bo Ifa. Aladikun Irumole Agba Ilua

Photos from Aladikun Adimula's post 01/06/2023

Aladikun Adimula Italeke. :Owonrin irosun /Owonyanrosun. :Orunmila so wipe Oja loja Owonrin, Gele ni gele Irosun, Eje Omo titun ni ko tan yanran yanran lori Ate, adifa fun Akoko tin loo gbawo ni ile Oniresa, Akoko ni ile wo lo n lo, emi lo ile iresa ni ile Obaadu, emi yio maa gbe lowo, emi yio maa pon leyin o, Atelewo Omo laa o sun oo. Aladikun Ita Oro tin kun yunmuyunmu Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 31/05/2023

Aladikun Adimula Italeke. :Eyonu Olodumare ni Agba Oore. Olodumare to ba semi lolowo emi yio maadupe Owo mejeeji ni Erukuku fin dupe lowo Eleyoro oka. Ifa to ba semi ni onire gbogbo emi yio maa dupe lowo reo, Owo mejeeji ni Erukuku fin dupe lowo Eleyoro oka. Aladikun Adimula mo dupe temiooo.

Photos from Aladikun Adimula's post 31/05/2023

Aladikun Adimula. Ofun Eko:Orunmila so wipe Yimiyimi lo su ose ni ko ri eni ti yio raa, adifa fun Orunmila ti yio maa rin ti yio ko rere Lona, Ifa wii o ni moko ewe Adesinkun Akoko eni rere ni Ope Asinla ko maa gbewa ko eni rere. Aladikun Italeke ibaaaaa

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun Adimula Italeke Oba edu Lagos. :Owonrinsogbe:'Eja todan ni won fii bo Ori Olu, eyi yangiyangi ni Esu gba, Agbon isale ni won fii ke gbami gbami arayi eni to wipe kagbani laagba, arayi eni to wipe kagbeni laagbe, Ifa logiriyanda Ifa lo to nii gba nii gba nii, Ori logiriyanda, Ori lo to nii gba nii gbani. Olodumare Eleda pelu Ori yio maa gbewa oooo. Aseooooo. Aladikun Adimula Italeke Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun Irumole Agba Ilua. :Owonrin Omoobatutu/Owonrin Laagan.:laagan lo oko komu ina lowo, ebipa laagan bii ki laagan ko ku, Aranse lo odo ko mu Akerengbe lo odo, ebipa Aranse bii ko lo orun Alakejin, laagan ko ni ku o, Aranse ko ni se bee ko lo Orun Alakejin, Adifa fun AdeOrose tin lo Ogun Otuyegbeyegbe. Ifa so wipe isegun ota. Ki Eda Eniyan bee maa ka nnkan kun. Aladikun Italeke Omo Orosola Ilua. Ita omo Oro tin pa igi, Oro tin pa ope, Aladikun Adimula Italeke Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun Adimula Oba edu Lagos. :Irosun Ate/Irosun Onjo:'Orunmila Aladikun so wipe Alaje igba igba n gbaniloju, Alaje Opon, Opon n pon niloju, Babalawo awo lokifa fun awo, awo waa tenubo fa nigbayio, bi Ojumo bamo awo a we, awo a si jeun. Olodumare Eleda pelu gbogbo Irumole a je ki a ri ere ile Aye je, Aladikun Agba Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun Adimula Oba edu Lagos. :Irosun Ate/Irosun Onjo/Irosun Oba:Orunmila so wipe igbaamisonu molodi oropo, Awomisonu molodi oropo, Ohun eni kii sonu ki ohun ko nu eni, adifa fun Onjo Amokoko ara ni won da lo si ode Oyo, adifa fun Onjo Amokoko Ola Omo Amo Ape fun Oba, Ara ni won da lo si ilu Oyo laye Atijo, gbogbo idije ti awon Oba Alade se ni igba naa ni ilu Oyo Alaafin, Oba Onjo lo gba ipo kinni ni ilu Okeho, gbogbo ara ti ilu kookan da ni Oyinbo to wa si odo Alaafin ni ki won ri gbogbo re mo inu ile, tio badi Odun meta Oyinbo ki won waa gba esi idanwo. Ikoko Amo Onjo ni kan lo duro dingbindingbin. Idi niyi ti omo bibi ilu Okeho fi maa se Olori lati Ayebaye awon BabaNla won. Aladikun Adimula Oba Edu Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun ibaaaa, Oyeniyi ibaaaa. Aladikun Adimula Oba edu Lagos. :irosun awoye/Irosun Alawoye, :Amiwo aja awo oloyo, adifa fun oloyo ti won ni ko bo Ori re tin lo bo Ado, a ni ko bo Ori, n lo bo ado, a se oogun lo ni ojo kan iponju, Ori eni lo ni ojo gbogbo. Olodumare Eleda pelu Ori yio maa fi ire fun waooo. Aladikun Oosa Ilua.

Photos from Aladikun Adimula's post 26/05/2023

Aladikun Adimula Oba edu Lagos. :Irosunturupon/Irosun Etutu. ;Orunmila so wipe tutudundun, tutunini, adifa fun Osuparogodo ti won ni ko ru ebo iyin kari Aye. Olodumare Eleda pelu gbogbo Irumole a je ki ile Aye san funwa, a o maa gba iyin lojoojumo lase Olodumare ati Orunmila Asiwaju rere. Aladikun Adimula Irumole Ilua.

Want your business to be the top-listed Beauty Salon in Sango Otta?
Click here to claim your Sponsored Listing.

Category

Telephone

Website

Address

39 Alafia Street, Ilogbo Ota
Sango Otta

Opening Hours

Monday 09:00 - 17:00
Tuesday 09:00 - 17:00
Wednesday 09:00 - 17:00
Thursday 09:00 - 17:00
Friday 09:00 - 17:00
Saturday 09:00 - 17:00
Sunday 09:00 - 17:00